FEC bowolu sise agbekale ile-iwe giga fafiti awon omo ogun - 9ja Olofofo

Breaking

9ja Olofofo

The No.1 Infotainment blog

Post Top Ad

Sunday, April 15, 2018

FEC bowolu sise agbekale ile-iwe giga fafiti awon omo ogunIgbimo torokan gbangban, FEC ti bowolu sise agbekale ile-iwe giga fafiti awon omo ogun (Nigerian Army University)  nilu Biu ti o kogun si ariwa ipinle Borno, Naijiria.
Igbimo ohun bowolu sise agbekale ile-iwe fafiti naa lasiko ipade apero awon torokan gbangban ti o waye lojoRU(Wednesday), eyi ti igbakeji aare omowe Yemi Osinbajo dari re.
Minisita to n ri si sise eto ile-iwe, ogbeni Adamu Adamu, lo kede oro naa lasiko to n yanana abajade oro ohun fun ile igbimo asoju sofin.
Adamu so pe, sise agbakale ile-iwe giga fafiti naa yoo se anfani pupo lati ni awon omo ogun ti o kaju osuwon.
Lara idagbasoke ti o tun farahan ninu ipade ohun, igbimo naa tun bowolu pipari ile eko otooto meji ati gbagede igba afe ni ipago awon olopaa ti o wa nipinle kano, eyi ti apapo owo ti won yoo lo je òjìlénígba dín mẹfa milionu owo naira (N234 million).
Sise agbekale Ile-iwe giga fafiti naa yoo wa ni ibamu pelu ofin ati ilana  agbekale ile-iwe giga todun 2010, ni eyi ti akeko yoo ni eto si iwe-eri leyin gbogbo saa re ti o ba lo lati fi keeko.
Bakan naa, ajo to n ri si sise agbekale ile-iwe giga fafiti Nigerian Universities Commission ni yoo se abewo ise akanse ohun ti o ba pari.

No comments:

Post a Comment

FcTables.com