Ibugbamu ado-oloro seku-pa eniyan marun un ni Somalia - 9ja Olofofo

Breaking

9ja Olofofo

The No.1 Infotainment blog

Post Top Ad

Sunday, April 15, 2018

Ibugbamu ado-oloro seku-pa eniyan marun un ni SomaliaO kere tan eniyan marun un lo ba isele ibugbamu ado oloro  ti o waye lakoko ifesewonse ni papa isere kan ti o wa ni guusu orile-ede Somalia lojoBo(Thursday).
Gege bi agbenusoro fun ile-ise olopaa, Mohamed Aden ati asofin Mahad Dhoore se so, won ni,  isele ohun lo je akoko iru re ti yoo waye ni papa isere lorie-ede naa.
Ibugbamu ohun waye ni agbegbe Barawe, lakoko ti ifesewonse lo lowo, bee si ni ile-ise olopaa fi mule pe, o seese ki o je awon omo ogun olote al Shabaab lo wa ni idi isele n la ibi ohun.
Ile-ise olopaa so pe, o farahan pe ero igbalode latona ti a mo si (remote control), ni awon dari ado oloro naa.
Gege bi asofin eka guusu orile-ede naa, Mahad Dhoore,  se so fun awon akoroyin“ibugbamu ohun seku-pa eniyan marun un ti awon miran si farapa yanayana lori papa isere naa. Opo lara awon ti o ba isele ohun lo ni awon oluworan ololufe bolus,”  
“A nigbagbo pe, omo ogun olote al Shabaab lo wa ni idi isele yii, bee si ni o farahan pe ero igbalode latona ti a mo si (remote control), ni won lo lati fi dari ado oloro naa,”  
Omo ogun olote Al Shabaab lo n ja ijagbara lorile-ede naa lati da ijoba ti won sile, ni oye ti ti won ti won tunmo si ofin islam.
Omo ogun olote Al Shabaab ohun, lo n se ikolu lorisirisi si olu ilu orile-ede naa ti n se Mogadishu ni gbogbo igba, ti o fi mo awon ibi miran ni Somalia.
Gege bi aare Mohamed Abdullahi Mohamed se so, lasiko to n kedun iku awon oloogbe naa,“omo ogun olote islam Al Shabaab lo wa ni idi ibugbamu ado oloro naa. Al Shabaab nikan ni ota ti a ni to n da wa laamu,”

No comments:

Post a Comment

FcTables.com