WHO ati ile-ise eto-ilera yoo fun awon akoroyin lami eye - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Sunday, 1 April 2018

WHO ati ile-ise eto-ilera yoo fun awon akoroyin lami eyeAjo ti o n ri eto ilera lagbaye, World Health Organisation (WHO),ati ile –ise ti o n ri eto-ilera lorile-ede Naijiria Nigerian Ministry of Health, n gbero ati da awon akoroyin leka eto-ilera lola.
Won soro ohun di mimo, nibi eto idanilekoo olojo meji fun awon akoroyin eka eto-ilera nilu Abuja.
Erongba idanilekoo ohun ni lati lati la awon akoroyin eto-ilera loye, lori ipa  ribi-ribi ti ajo WHO n ko lorile-ede Naijiria.
Asoju ajo WHO lorile-ede Naijiria, Dokita Wondimagegnehu Alemu, salaye pe, idanilekoo ohun ni lati gba awon akoroyin eka eto-ilera niyanju lori bi won yoo se maa gbe iroyin ojuse ajo WHO jade, nipa akitiyan ati atileyin won lorile-ede Naijiria.
Ni abala tire, dokita ajo WHO Rex Mpazanje ro awon akoroyin lati lo igbese yii lati ji giri ninu gbigbe iroyin eto ilera.
Ninu oro iranse minisita fun eto ilera lorile-ede Naijiria, ojogbon Isaac Adewale so pe, oun fara mo ami eye idalola naa lati fi se kori ya fun awon akoroyin ti won gbe iroyin eka eto-ilera, eyi ti ajo WHO se agbekale re, ni eyi ti o seleri lati se agbateru abala kan ninu ipele ami eye naa.
O wa ro awon akoroyin nibi idanilekoo naa, lati maa se ojusaaju tabi figbakan-bokan ninu iroyin won.
O salaye pe, iroyin won yoo je ki ijoba ati awon ara-ilu ni agboye ohun ti o n sele ati awon ipenija to o n koju eka eto-ilera naa.
Ojogbon Adewale fi kun oro pe, gbogbo iroyin ti won ba gbe sita ni won yoo iyanju si.
Minisita ohun eni ti alukoro ile-ise naa abileko Boade Akintola wa ro awon akoroyin naa lati se ojuse ti o to, nipa fifun awon omo orile-ede Naijiria ni iroyin ti yoo mu igberu ba eka eto-ilera.
Ti awon eniyan ba n gbo iroyin otito ati gbigbe igbe aye tooto, adinku yoo ba itankale aarun, awon eniyan yoo si maa gbe igbe aye alaafia.
Akori idanlekoo ohun dale: Awon akoroyin, ojuse ati iroyin eka eto-ilera lorile-ede Naijiria, eyi ti ojogbon Pate ti ile eko giga fafiti Bayero  safihan awon ipenija ti o n koju  awon akoroyin, lara eyi ti a ti ri: ainimo ijinle nipa ise won to, ipolowo-oja, aisi amojuto to peye, aini ife si oro to n sele leka eto-ilera ati awon oro miiran gbogbo.
Awon akoroyin ti won kopa ninu idanilekoo naa ni won wa lati ile-ise iroyin atewe-ta, ile-ise iroyin radio, ero amohun-maworan ati awon akoroyin ori ero ayelujara.

No comments:

Post a Comment