Aare Buhari ro egbe oselu APC lati jawe olubori - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 19 May 2018

Aare Buhari ro egbe oselu APC lati jawe oluboriAare Muhammadu Buhari ti ro awon toro kan gbongbon ninu egbe oselu All Progressives Congress APC lati sise takuntakun lojuna lati jawe olubori ninu eto idibo gomina ipinle Ekiti ti yoo waye lojo kerinla osu keje odun ti a wa yii.
Aare so oro ohun laale ojoRu(Wednesday) nile ipinle naa, lasiko ipade apeje re pelu awon adari egbe oselu ohun ati awon oludije dupo patapata nipinle Ekiti.
Aare Buhari so pe, a gbodo sise po lati ri pe, a gbegba oroke ninu idibo ohun.
“Mo ranti awon nkan ti o sele seyin, ti a fi padanu ipo gomina nipinle Ekiti lodun 2014. A ni lati sa gbogbo ipa wa lati ri daju pe, a ko fayegbe irewesi bi o ti le wu ko mo.
Ni bayii ti a ti ni oludije wa, a ni lati fowosowopo lati ri pe, egbe yii jawe olubori ninu eto idibo ohun.”

Ipade apeje aare Buhari pelu awon adari egbe oselu APC nipinle Ekiti

Ni bayii, eto idibo tiwa ti pari, ti a si ti pese ondije dupo gomina, ohun ti o kan bayii ni ki, awon adari egbe oselu APC fowosowopo lojuna lati gbe egbe oselu APC jawe olubori ninu olokan-o-jokan eto idibo to n bo lona.

Lara awon ti o wa sibi apeje ohun ni: igbakeji aare, ojogbon Yemi Osinbajo, alaga egbe osleu APC, Odigie Oyegun, adari egbe naa, Bola Ahmed Tinubu, adari egbe ohun ti eka awon ipinle ti o kogun si iwo oorun, Bisi Akande, awon minisita ati gomina awon ipinle lorisirisi naa ko gbeyin, ti o fimo awon ti o dije dupo ohun méjílélọ́gbọ̀n ninu egbe oselu naa nipinle Ekiti.

No comments:

Post a Comment