Ijoba orile ede Gabon kowe fipo sile - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Thursday, 3 May 2018

Ijoba orile ede Gabon kowe fipo sileIjoba orile ede Gabon ti kowe fipo sile lojo Isegun leyin ti ile-ejo tu ile-igbimo asofin ka, ti ile-ejo naa tun pase fun awon adari orile ede naa lati fi ipo sile nitori pe won sun eto idibo siwaju.
Iroyin so pe “adari ijoba orile ede naa, Emmanuel Issoze-Ngondet kowe fipo ijoba sile leyin igba ti ile-ejo ti se ipinnu lati fopin si ile igbimo asofin”.
Ile-ejo so pe, o ye ki ijoba ti sun eto idibo naa siwaju leemeji  ki o to di ogbon ojo osu kerin.Nitori naa, ile-igbmo  asofin agba ni yoo maa sakoso ile-igbimo asofin kekere titi ti won yoo fi dibo .ile-ejo tun so pe won yoo kede igba ti eto idibo naa yoo waye.
Lodun 2016, ti aare Bongo tun pada wole gege bi aare orile ede naa ni awon alatako ti n fi esun kan ijoba re pe , o se mago-mago nipa eto idibo re.
Leyin idibo ni wahala be sile ti awon alatako si so pe àádọ́ta eniyan lo ti ku nibi isele naa,sugbon iroyin lati odo ijoba so pe eniyan mẹ́ta lo ku.
Bongo gba ipo lowo baba re Omar Bongo,ti o ti fi igba kan dari orile ede naa fun odun mọ́kànlélógójì, ki o to ku ni odun 2009.
Orile ede Garbon ni epo robi, ohun alumooni ile ati igi gedu , owo to si n wo apo orile ede naa le ni ilopo merin orile ede miiran.
Ida meta ninu ogorun un awon omo orile ede naa ti iye won le ni milionu kan lo n gbe ninu osi.

No comments:

Post a Comment