Super Eagles nilo atileyin ti o peye saaju idije agbaye - Dalung - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 19 May 2018

Super Eagles nilo atileyin ti o peye saaju idije agbaye - DalungMinisita to n ri si oro ere idaraya ati idagbasoke awon odo ni Naijiria, ogbeni Solomon Dalung ti pe fun atileyin ti o lelegbe latowo awon omo orile-ede yii ati ajo NFF fun aseyori iko agbaboolu Super Eagles saaju idije agbaye to n bo lona lorile-ede Russia.
Dalung so ninu oro re eleyi ti amugbalegbe pataki re lori oro igbodegba ati ifitonileti, Nneka Ikem-Anibeze, gbe jade lojoBo(Thursday) nilu Abuja, O gboriyin fun iko ohun fun gbogbo akitiyan won, ibasepo ati iwa akinkanju ti won ni saaju idije naa to n ti n sun mole bayii .
O wa ro, apapo iko ohun ati awon toro kan ninu iko naa pe, ki won ri daju lati kopa daradara ninu olokan-o-jokan ifesewonse olorejore won ti won yoo gba fun igbaradi ni kikun saaju idije nla naa.
 “Mo gbosuba kare lai fun ijoba apapo lataari atileyin won lolokan-o-jokan  fun iko yii.
“Ijoba fi da awon omo orile-ede loju lati seto bi o ti to ati bi o ti ye saaju awon ifesewonse olorejore wa yooku ti a o gba pelu, DR Congo, England ati Czech Republic.’’
Bakan naa, minisita tun ki ajo NFF, awon osise ti o fi mo awon akonimoogba gbpgbo fun akitiyan won, bee si ni, O ro won lati pa okan won po sojukan fun igbaradi idije naa.

No comments:

Post a Comment