WHO pe fun ipade pajawiri lataari arun Ebola - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Saturday, 19 May 2018

WHO pe fun ipade pajawiri lataari arun EbolaAjo to n mojuto eto ilera lagbaye World Health Organisation (WHO), ti pe fun ipade pajawiri lati jiroro nipa ona ti won yoo gba fi dena bi arun Ebola to gbode kan lorile-ede Democratic Republic of the Congo ko se ni tan kakaakiri.
Oro ohun waye leyin bi won se tun sawari arun ohun nilu Mbandaka, ilu ti o kun fun opolopo eniyan ti o le ni milionu, eleyi ti o mu iberu gbojo jade ki arun naa ma lo tan kakaakiri olu ilu orile-ede ohun ti n se Kinshasa tabi awon orile-ede miiran.
Ni bayii, ajo WHO ti n gbero lati pin abere ajesara eyi ti yoo dena arun asekupani ohun ki o to tan kakaakiri, bakan naa si ni, o hun ti o tun le je ipenija ni, ibi ti o tutu ti won yoo ko abere ajesara naa pamo si, eleyi ti ina monamona ko se deede ninu ilu naa.
Ewe, eyi je igba kesan an bayii ti arun Ebola yoo be sita lorile-ede DR Congo lati odun melo kan seyin ti won ti sawari arun ohun letido abule kan.

No comments:

Post a Comment