Aare Buhari, Saraki kẹdun iku alaga ajọ ICPC tẹlẹri. - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

ADS


Tuesday, 5 June 2018

Aare Buhari, Saraki kẹdun iku alaga ajọ ICPC tẹlẹri.


Aare Buhari, Saraki kẹdun iku alaga ajọ ICPC tẹlẹri.
Aare orile ede Niajiria Muhammadu Buhari ti kedun iku  eni akoko to je alaga fun ajo to n ri si  sise owo ilu kumo- kumo teleri  lorile ede Naijiria; Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission (ICPC),adajo agba Mustapha Akanbi,Aare sapejuwe oloogbe naa  gege bi olooto ati olufokansin eniyan.
Won sin oloogbe Mustapha Akanbi, lojo Aiku nile re to wa ni Ilorin,ni ipinle Kwara.Imam agba to wa niluu Ilorin, Muhammed Soliu Bashir ati awon onimo ninu eko Islam lo wa nibi adura ikeyin naa.
Aare so pe  orile ede Naijiria ko ni gbagbe ise  rere ti oloogbe Akanbi ti se lorile ede Najiria lati je ki iwa otito ati ibowo fun ofin ni ajo idajo lorile ede Naijria.
Gege bi aare se so, “ki won bowo fun eniyan nitori iwa ooto ati ifokansin, je ogún ati ohun molegbagbe  ti eniyan lee fi sile .”
“Ni orile ede ti iwa ibaje ti gbile bi ewu , Akanbi ya ara re soto gege bi eni to feran  ooto ati  ifarasin dipo ife owo lenu ise re”.
Aare tun so pe  “Akinkanju eniyan , bi I Akanbi ko nifee si iwa ibaje nitori pe iwa ibaje gbode kan tabi to gbile  laarin awon eniyan”.
Aare Buhari wa ba awon eniyan ipinle Kwara ati gbogbo awon omo ilu Ilorin kedun iku oloogbe naa.
Bakan naa, ni awon omo orile ede Naijiria, si n kedun iku oloogbe naa.Abenugan ile igbimo asofin agba Bukola Saraki naa ti  fi oro ikedun re sinu ero twitter re.”
inu mi baje pe baba Akanbi ti fi wa sile . o je eni ti ko beru eniyan , ti o si maa n so otito oro.O da bi baba fun mi. Ipinle Kwara ati orile ede Naijiria yoo  maa se iranti re.  ki Olorun alagbara julo, Allah (SWT)fi baba si aarin awon olododo eniyan.
Aljannah Firdaus. 
Omowe Ahmed so pe “gbogbo odun ti adajo agba Akanbi lo lori eto idajo ati alaga ICPC  ni ko fi lowo ninu iwa ibaje,iwa akinkanju re lori eto ijoba rere ati itesiwaju ni agbegbe re ,ko ni pare ninu iwe itan orile ede  Naijiria.
Bakan naa, abenugan fun ile igbimo asofin fun ipinle Kwara omowe Ali Ahmad naa sapejuwe adajo agba ana,ninu iwe ikedun ti oun naa gbe sita,  gege bi okan lara awon adajo to dara julo ni ajo eto idajo, lorilede Naijiria.
O so pe “oloogbe Mustapha Akanbi je olukose rere fun awon musulumi, ati eto idajo . O tun je elesin tooto ati adari rere fun awon agbejoro ati adajo lorile ede Najiria.Adura wa ni pe ki Olorun dari ese ati awon a-se-deede re jin in, ki Olorun si fun un ni Al-janah Firdaos.”
Bakan naa, alukoro fun egbe APC Mallam Bolaji Abdulmalihi naa baa won ebi oloogbe Mustapha Akanbi kedun.
Mallam Abdullahi sapejuwe oloogbe Akanbi gege bi eni to nifee si alaafia, otito ati ola, gege bi agbejoro ati adajo , o ko ipa pataki lori idagbasoke eto idajo lorile ede Najiria.
“lasiko to je alaga akoko  fun ajo to n ri si sise owo ilu kumo-kumo , o fi ipa rere  sile fun ajo naa, opolopo awon oniwa ibaje lo gbe lo sile ejo.”
“oloogbe Akanbi je olooto , ti ko si ni iwa ojusaaju fun awon eniyan.Bo tile je pe omo orile ede Naijiria ni, sibe o ko ipa ipataki ninu idagbasoke ipinle Kwara.”
Abdulallahi so pe “ o seni laaanu pe ,lasiko to ye ki awon eniyan maa bu omi ogbon re mu, ni iku mu un lo, ki Olorun te e si afefe ire.”
A bi oloogbe Mustapha Akanbi ni ojo kokanla,osu kesan an ,odun 1932 ni Accra to je orile ede Ghana.
Aare ana  fun orile ede Naijiria , Olusegun Obasanjo si yan an gege bi  alaga fun ajo ICPC lodun 2000 titi di odun 2005.

No comments:

Post a Comment