Ijoba dide si oro awon akekobinrin ti won n korin nihoho ni South Africa - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Monday, 4 June 2018

Ijoba dide si oro awon akekobinrin ti won n korin nihoho ni South Africa

Minista fun eto eko lorile ede South Africa ni iwadii ti bere lori oro awon akekobinrin kan ti won korin nihoho.

Angie Motshekga to je minista fun eto eko ni oro awon omobinrin Xhosa naa ba ni ninuje pupo pe won le wo iledi ‘inkciyo’ lasan fi maa korin ni eyi to tako asa iponraenile ile Adulawo lapapo.
Alakoso egbe akorin naa ti won ko so oruko re ni ori oun wu si bi awon omo naa se se daadaa nitori pe iran Xhosa lo ni orin kiko ati inkciyo iledi ti awon akekoobinrin naa wo.
Iran Xhosa ni eya keji to tobi julo ni South Africa. Nibi idije kan ni ila oorun Cape, ni Mthatha ni won ti korin naa lose to koja ti fonran fidio n safihan oyan ati idi awon omo naa gi Times live se so.
Bayii, iwadii ti bere lori oro naa ni eka Motshekga pelu erongba pe ko sohun to buru ninu ipolongo asa iran Kankan sugbon kii se ki a maa foju egbo tele rin kiri lai mo eto awon akekoo.

No comments:

Post a Comment