Naijiria safihan awon aseyege re nibi ipade IPI - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Monday, 25 June 2018

Naijiria safihan awon aseyege re nibi ipade IPIAwon minisita lorile ede Naijiria ti salaye nibi ipade agbaye awon oniroyin ati akoroyin to n lowo  niluu Abuja, pe  ijoba ti se gudugudu-meje , yaya mefa lati mu igbe aye iderun ba awon omo orile ede yii.
Nigba ti minisita fun eto inawo lorile ede Naijiria, Kemi Adeosun n soro nibi ipade agbaye naa pe:’’ijoba n mu ohun amayederun lokunkundun.A n se oju ona oko ati oju irin leekanaa lati mu igberu ba eto oro aje.A tun ti pese anfaani  fun awon ile-ise ijoba lati le satunse si oju ona oko nipa lilo owo-ori, ni eyi ti igberu yoo fi de ba eto oro aje.’’
O tun salaye pe ijoba naa n se ojuse re lori eto agbe nipa pipese ida ogun ninu ogorun un lodun , ida mewaa ninu ogorun un, ni  won fi si owo epo robi.
Minisita fun oro ile-ise,okoowo ati idokoowo, omowe Okechukwu Enalemah so fun awon asoju nibi ipade naa pe orile ede Naijiria ko towobo adehun okoowo ofe nitori pe , awon ti oro naa kan , ko mo nipa oro naa.
O so pe aare orile ede Naijria ti so pe ki won je ki  gbogbo awon ti oro naa kan lowo ninu eto naa, ki oro naa ma baa da wahala tabi ede ayede sile , ni eyi ti o lee fa akoba si eto oro aje orile ede yii.
O tun tesiwaju pe ibasepo to wa laarin orile ede Naijiria ati orile ede China je ohun ti o dara, paapaa julo fun itesiwaju orile ede Afirika.
Minisita fun iroyin ati asa Lai Mohammed, naa tun so pe iyipada oju-ojo ati iyangbe ile lo n fa wahala to maa n sele laarin awon odaran ati agbe lorile ede Naijiria.
O ni:’’iru isele bayii ko je ohun tuntun nitori pe o ti sele lodun 1947 ri, sugbon iyipada oju-ojo lo tun je ki wahala yii tun po si, nitori ile ati awon ohun alumooni ile ti ko tun to.’’
O tun tesiwaju pe ohun to le tan isoro yii ni ki awon eniyan fi aaye gba ara won, o wa ro awon eniyan lati gba imo ero tuntun laaye paapaa julo nipa pipese ogba ijeran.
Minisita fun iroyin tun wa salaye fun awon asoju pe ijoba ti mu awon ileri re se lorile ede Naijiria ,paapaa julo nipa pipese eto aabo, ni awon apa ibikan ti awon omo –oogun olote ti gba tele.
isoro eto aabo
Minisita fun oro abele , Abdulrahman Dambazau so pe ijoba n mu ohun amayederun lokunkundun,lati fi koju isoro airise ati eto aabo lorile ede Naijiria.O tesiwaju pe awon ala to wa lorile ede Naijiria ko dara rara , nitori eto ti ajo ECOWAS se lati fun awon eniyan ni anfaani lati  maa wole-jade bo se wu won.
O so pe ijoba orile ede Naijiria,yoo mojuto lilo  imo ero fun ala ile  ati lati loo fun awon ala to pa orile ede Naijiria ati awon orile ede miiran papo.Ijoba yoo tun se ohun amoriya fun ajo to n mojuto bi awon eniyan se n wole –jade lorile ede Naijiria lona ti won yoo fi lee maa gbokun ti bi awon janduku ati odaran se n wole sorile ede Naijiria.
O tun so pe “A n fowosowopo pelu Ajo Europe ati awon ajo miiran , pelu awon amuleti wa lati koju isoro to n dojuko awon ekun orile ede Afirika.’’
Lori oro eto aabo, minisita wa ro awon gomina lati mojuto eto ijoba rere , ki won si  dekun lati maa fesun kan ijoba apapo tabi ajo eleto aabo.
“eto ijoba rere ni ojutuu si awon isoro ti a n koju ni awon apa ibikan lorile ede yii;ti eto ijoba rere ba wa, o daju pe gbogbo awon isoro ti a n koju ni yoo di afiseyin ti eegun n fi aso.’’
John Momoh, alaga fun egbe akoroyin lorile ede Naijiria lo dari ijiroro naa.

No comments:

Post a Comment