APC- Abajade eto idibo ipinle Osun ko waye ki a le ba ri ojureere - The No.1 Infotainment blog

Breaking

The No.1 Infotainment blog

The No.1 Infotainment blog

Wednesday, 26 September 2018

APC- Abajade eto idibo ipinle Osun ko waye ki a le ba ri ojureereEgbe oselu ti o wa lori aleefa lowo bayii, All Progressives Congress, APC, ti benu ate lu esun ti won fi kan egbe naa pe abajade eto idibo gomina ipinle Osun waye lati fi ran egbe APC lowo ni.
Lataari ikede ajo INEC, eleyi ti egbe oselu alatako Peoples Democratic Party, PDP n gbe igba oroke lowo pelu ibo ọ̀ọ́dúrún le metaleladọta, ti  fesun kan ajo INEC pe won se ojusaaju ni erongba lati ran egbe oselu APC lowo ni.
Ninu oro ti adele akowe agba eka iforotonileti egbe oselu APC, ogbeni Yekini Nabena, gbe jade. O ni, abajade naa waye lai fi igba kan bo kan ninu lataari bi eto idibo ohun se lo.
Egbe oselu APC gboriyin fun ise takun-takun ajo INEC ninu eto idibo ohun.
Bakan naa, egbe oselu “All Progressives Congress (APC) tun gboriyin fun awon osise alaabo ati awon ajo miiran ti o tun kopa fun aseyori eto idibo akoko ohun.
Ewe, Bi a se n tesiwaju lati tun mu igberu ba eto idibo lorille-ede yii, bee si ni lati maa faye gba ojusaaju ninu awon idibo wa gbogbo, egbe oselu APC gbosuba fun isejoba aare Muhammadu Buhari, papaajulo fun akitiyan re lati je ki eto idibo waye nirowo-rose, bee si ni lai figba kan bo kan ninu.

No comments:

Post a Comment